Ẹ Wá Ẹ Jẹ́ Ká Yin Olúwa

(Wednesday, 11th March 2026)

[Chorus]
Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yin Olúwa Ọlọ́run mi,
Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ ló mú wa dé òní;
Ó fọ́ ìdè irin,
Ó ṣẹ́gun ikú,
Èmi yóò máa jó, èmi yóò máa kọrin,
Màá fi iyìn fún orúkọ Rẹ.


[Veese 1]
Tẹ́lẹ̀ mo ti kú nínú ẹ̀ṣẹ̀,
Ṣùgbọ́n Jèhófà rán Jésù Kristi;
Ó rà mí padà kúrò lọ́wọ́ ikú,
Ó sì gbà mí kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀;
Èmi yóò máa jó, èmi yóò máa kọrin,
Màá fi iyìn fún orúkọ Rẹ.

[Chorus]
Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yin Olúwa Ọlọ́run mi,
Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ ló mú wa dé òní;
Ó fọ́ ìdè irin,
Ó ṣẹ́gun ikú,
Èmi yóò máa jó, èmi yóò máa kọrin,
Màá fi iyìn fún orúkọ Rẹ.


[Verse 2]
Kí ni màá fi san fún Ọ, Baba?
Wúrà ati fàdákà kò yẹ́ fún Ọ;
Bí mo bá sè oúnjẹ fún Ọ,
Iwọ kì í jẹun bí ènìyàn;
Ìyìn nikan l'O bèrè lọ́wọ́ mi,
Èmi yóò máa jó, èmi yóò máa kọrin,
Màá fi iyìn fún orúkọ Rẹ.

[Chorus]
Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yin Olúwa Ọlọ́run mi,
Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ ló mú wa dé òní;
Ó fọ́ ìdè irin,
Ó ṣẹ́gun ikú,
Èmi yóò máa jó, èmi yóò máa kọrin,
Màá fi iyìn fún orúkọ Rẹ.


[Verse 3]
Mi ò tíì rí Ọlọ́run bí Iwọ,
Tó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu nlá;
Ọwọ́ Rẹ̀ ń gbà àwọn ọmọ Rẹ là,
Lójoojúmọ́ O ń ṣe ìgbàlà;
Ìbá ṣe pé ayé mọ rírì Rẹ,
Èmi yóò máa jó, èmi yóò máa kọrin,
Màá fi iyìn fún orúkọ Rẹ.

[Chorus]
Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yin Olúwa Ọlọ́run mi,
Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ ló mú wa dé òní;
Ó fọ́ ìdè irin,
Ó ṣẹ́gun ikú,
Èmi yóò máa jó, èmi yóò máa kọrin,
Màá fi iyìn fún orúkọ Rẹ.


[Verse 4]
Nígbà tí mo wà láyé yìí,
Mi ò ní dá íyin Rẹ dúró;
Nígbà tí ẹ̀mí ṣì wà lára mi,
Èmi yóò máa yin Ọ lálẹ́ at'òru;
Ohunkóhun tí ówù tíì bá jẹ́,
Èmi yóò máa jó, èmi yóò máa kọrin,
Màá fi iyìn fún orúkọ Rẹ.

[Chorus]
Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yin Olúwa Ọlọ́run mi,
Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ ló mú wa dé òní;
Ó fọ́ ìdè irin,
Ó ṣẹ́gun ikú,
Èmi yóò máa jó, èmi yóò máa kọrin,
Màá fi iyìn fún orúkọ Rẹ.


[Verse 5]
Ayé mi kò ní ìtumọ̀ láìsí Rẹ,
Ìwọ ni Ìbẹ̀rẹ̀ àti Òpin mi;
Bí ayé asán yìí bá ré kọjá,
Èmi yóò bá Ọ gbé títí láé;
Ní ayérayé màá máa yìn Ọ,
Èmi yóò máa jó, èmi yóò máa kọrin,
Màá fi iyìn fún orúkọ Rẹ.

[Chorus]
Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yin Olúwa Ọlọ́run mi,
Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ ló mú wa dé òní;
Ó fọ́ ìdè irin,
Ó ṣẹ́gun ikú,
Èmi yóò máa jó, èmi yóò máa kọrin,
Màá fi iyìn fún orúkọ Rẹ.


[Final Chorus]
Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yin Olúwa Ọlọ́run mi,
Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ ló mú wa dé òní;
Ó fọ́ ìdè irin,
Ó ṣẹ́gun ikú,
Èmi yóò máa jó, èmi yóò máa kọrin,
Màá fi iyìn fún orúkọ Rẹ.

Share this Page!

"Seek the Lord while He may be found, call upon Him while He is near. Let the wicked forsake his way, and the unrighteous man his thoughts; let him return to the Lord, and He will have mercy on him; and to our God, for He will abundantly pardon." Isaiah 55:6-7

Contact Info

info@jesudairo.world
webmaster@jesudairo.world

+44 7405 436304
+234 90 7937 4685

If a man breathes his last breath, his Spirit departs and continues his life elsewhere. Whatever life he lives here will determine his destination and how his next life will be.

@pastorjesudairo

App Downloads

You can download our apps below



© Copyright 2026 Jesudairo - The Word Of God - Proclaiming the word of God -  All Rights Reserved